Sei sulla pagina 1di 22

IWE ETO

ADURA
AWON WOLI
LATI OWO
WOLI M.O AGBARAMIKO

APA KINNI
©WOLI MICHEAL O. AGBARAMIKO
ITEJADE AKOKO WAYE NI ODUN 2018

PUBLISHED BY
GOD IS ABLE PUBLISHERS CENTRE

08185386093, 08091198826

Email: agbaramiko@gmail.com

prophetmichealagbaramiko@yahoo.com
ORO IKILO

Ko si aye fun enikeni lati tun iwe yi dako, tabi tunse eda re ni ona

yowu, jowo ma se gbiyanju re, lati tun ko, nitori oni ewu pupo, fun

irufe eniti o ba se atunko iwe yii, boya lati fi pa owo si apo ara re, tabi

o se awon amulo awon nkan ti o wa ninu iwe yii, fun atunko ti are tie,

o lewu pupo, jowo je eleti omo.

Ti aba ri enikeni ti o tapa si ase yi, irufe eni be wa labe egun ati edidi ti

a fi ko iwe yii. Jowo ma si lero wipe, ti o ba se ko si eniti o ri o, ma

ranti wipe Elisah wi fun Gehasi wipe, oju mi ko ha nba o lo, nigba ti o

lo ba Namani, nitori idi eyi o gba idaji oju ese, edidi ti a tu kuro ninu

aye Namani, o si pada sinu aye Gehasi.

Jowo ma ranti wipe ile ti a fi tomo iri ni yoo wo.

Nitori idi eyi ma se se eda iwe yii lai gba ase lowo Woli ti o ko iwe yi. Ni

oruko Jesu Kristi o ni padanu ile ologo, ogun esu ko ni bori re. (amin)

Tiyin ninu ise Oluwa


Woli M.O Agbaramiko
KINI OHUN TI AN PE NI ETO
Ti a ban so nipa eto, eto tumo si itoni, igbese ati ona abayo, boya ti eniyan ba wa

ninu isoro kan, tabi ti eniyan nla nkankan koja eyiti o koja ogbon eniyan ati oye

eniyan. Nigbana ni ohun ti a pe ni eto le farahan.

Eyi si ma n waye lati owo idari ati itoni emi awon Woli, a ri opolopo awon Woli

ninu Bibeli ti Olorun dari won si eto ti won yo se fun ona abayo.

Ti a ba wo igbe aye Mose, Olorun fun ni awon eto pupo, ti o gbodo se, nigbati

Mose de odo Mara, Bibeli wipe omi je ohun ti o koro, awon omo Isireli si gbodo

mu omi, sugbon Mose kepe Olorun, Olorun si fun ni itoni ohun ti yoo se, iwe Eks

15:23-27, bakan na ninu aye Jakobu, Labani lo ogbon jibiti fun Jakobu nipa

wipe ki eran ma bi, oni awo kan, sugbon nigbehin Jakobu na gba itoni, o si se

eto ti e naa, Olorun si ti leyin. Ka iwe Gen 30:35-43 Woli Elisha na se eto tie,

gbogbo awon iranse Olorun ti gbadura si omi Jeriko, ko si ona abayo, sugbon ni

kete ti won de odo Woli Elisha o fun won ni eto ti won yo se, won si mu iyo sinu

awo koto, omi naa si di didun, ka iwe Awon Oba Keji 2:19-25, Jesu Kristi Oluwa,

naa se eto adura ti e naa, abi Okunrin kan afoju lati inu iya re wa, Jesu Kristi tu

ito sile o si fi se amo, o le mo oju re, o ni ki o lo we ni odo, o si gba iwosan, ka iwe

Johanu 9: 1-10.

Eto je itoni Olorun, lati owo awon Woli, bakan na ni o je igbese, Olorun le dari

Woli re si awon igbase ti eniyan yoo gbe, ti ogun aye re yo fi se. opolopo eto ni o

sele ninu aye Woli ni igbanni, ati ninu irin-ajo ise iranse Jesu, bakan na ninu

irin ajo awon omo ehin Jesu, sugbon pupo ni a o ko sinu iwe mimo nitori awon

idi kan.
1. ETO ADURA FUN OGBON, IMO ATI RIRANTI NKAN: A o se ise yii ni ojo Alamisi
tin se ojo Thursday a o gbawe ni ojo yii, a o ra eyin kan a o bo eyin naa a o so
sinu Cup titun kan, ti o ni Omi ninu, a o ka Psalm yii sinu re Ps 119: 9-16 , Deut
33: 4, Jos 1: 1-8, a o wa pe oruko mimo yi si inu re KOSNIEL, SKRUNNIEL,
MUPIEL, a o wa gbadura si, fun ogbon, imo ati oye, a o si se eto na ni dede
agogo mefa irole, ki ato je ounje, leyin na, a o wa je eyin na, a o si mu omi inu
Cup naa tan a o wa ka Psalm 119: 9-12, nigba meta, leyin na, a le wa lo jeun
ounje miran

2. ETO LATI LE EMI OKUNKUN KURO NINU ILE TABI NI ILE ITAJA: A o bu iyo
die sinu omi, a o ka Psalm 104 sinu omi naa, a o won omi na sinu ile a o ka
oruko Oluwa yi sinu omi naa, BAPABAPAJI, HOLY MICHAEL,HOLY GABRIEL,
HOLY RAPHEAL, HOLY URIER ROLLER, leyin na a o gbadura si igun ile naa, a
o si ka Psalm yi si awon igun ile na, Psalm 14, 43, 110, 114 ni arin ile na a o ka
iwe ifihan 12: 7-17, Mk 1:21-27, Isaiah 47: 1-15, leyin na a o gbadura, a o fi emi
aimo ati emi esu gbogbo bu.

3. ETO LATI PE OBINRIN TI O SALO PADA: A o gbe ile kekere ni enu ona, ti ile ti
arabinrin na ngbe, tabi ti o n sun si, a o si pe oruko Oluwa yi sinu ile na,
JEHOVA BAHABA TAHUBI BAHUBOH nigba meje ti o ba salo nitori ko si owo
lowo oko, ki e ka Ezk 16: 8-14, Isaiah 54: 4-17, 35, Gen 28: 15-19, Psalm 126,
20, 24, ki eni naa gbadura pe ki o pada wa si ile naa, ki o gbadura naa fun ojo
meje, ki a si tan imole ni ojo meje naa. Ti Obinrin naa ba lo nitori idi miiran, e je
ki a ka Ezk 16:8-14, 36: 23-28, Isaiah 35, Gen, 28: 15-19, Psalm 126, 20, 24. Ti
Obinrin naa ba ti pada wale, ki a di koto naa ki a si jo gbadura pupo pelu Psalm
yii 45, 26, 97, 140.

4. ETO ADURA ISEGUN OUNJE OJU ORUN

Ti aba lala wipe a je ounje oju orun, ti o ba ti taji, bu omi ti o le mu tan sinu Cup
ka Psalm yi si Psalm 114 nigba meje, ki o si pe oruko yii si JAH x 7, ti o ba tin ka
Psalm naa ni ki o ma pe oruko na pelu irele okan ki o ka Mk 16:17-20, Lk 10: 18-
19, ki o si gbadura, ki o wa mu omi na.

5. ETO ADURA LATI DE IPO OLA: Ki awa ike Bucket, ki a pon omi sinu re, ki a lo
wa imo ope eyo meje sinu omi naa, ki a wa ka Psalm yii sinu omi naa Psalm 92,
94, 23, 20, 24,10, 100 nigba meta, ki a wa pe oruko yi si JEHOVA ELOHIM X 7,
ki a si gbadura bi a se fe ki o ri fun wa, leyin na ki a lo fi omi naa we, e je ki a
maa se ni igba gbogbo, ona yo si la, a o si de ipo giga.

6. ETO ADURA FUN ASEYORI NINU IDANWO: Eni ti o fe se idanwo, yo ko oruko re


sinu iwe parchment paper tabi iwe felefele, a o si tun ko Ps 8: 1-9 ni ibi isale Ps
naa, bakana a o wa ko oruko Oluwa yi si abe re

JAH - JUBRILLAH
ELI - APPEJUBBA

ELI - AJJUBBAH

ELI - JAH – BUBBIH

ELI - ILAH

Leyin na a o daruko oruko eni na, ati ibi ti o ti fe se idanwo na, a o si pe oruko yi
JEHOVA ELISAITTAH X 3, leyin na a o dana sun iwe naa, a o pin eru iwe naa si
meji, apa kan yoo da sinu omi yo si mu, apa keji yo da sinu Olive oil tabi bintu yo
fi ma para lo si ile idanwo re

7. ETO ADURA LATI JI ENITI O DAKU DIDE: A o daruko Oluwa yi si ara eniti o
daku naa, enikeni ko gbodo gbo oruko naa, o lewu ti eti mii ba gbo nitori naa, pe
oruko na jeje

ELO I – RAKULLAJAH X 3

YAH – DI – JAH X 3

AJAGURRAITLABBI X 3

Ki a si gbadura ni orko baba ati niti omo, ati emi mimo, ki Olorun da emi ----------
--------- a o daruko eniti o daku naa, pe ki Olorun ki o ji dide.

8. ETO ADURA LATI SEGUN AWON OTA: Ti awon ota ba nyo o lenu, ka Ps yi sinu
iyo, bakanna kaa sinu atelewo re mejeji, Ps 125 x 7, ki o sip e oruko yi (JAH –
NISSI - YO) x 7, ki o sigbadura si igun mererin, leyin na ki o wa fun iyo naa ka si
igun mererin, o daju Oluwa yo tu awon ota re ka, iwo yoo si ni isegun.

9. ETO ADURA LORI AGBARA OKUNKUN TI ON TU IBUKUN WA KA, TI KO SI FE


KI OWO DURO LOWO WAE bu omi sinu ike bucket kan, ki e ka Ps 126 x 7 sinu
omi naa, ki e pe oruko yi ti e ba ti n ka Ps naa, WALLISIRRATTU, MUSSIRRA,
WASSILLITRATU, MUSURAH, ki esi gbadura si omi naa, ki ewa gbe sinu iri
moju, ni ojo keji ki e lo gbe omi naa, ki eto soro si eniyan. Ki e gbe wole, ki e si fi
omi naa fo owo yin, bakana ki e si fi we pelu. Iyato yoo wa.

10. ETO ADURA FUN IBIMO LAISI EWU :A o ma ka Ps 16 x 3, a o pe oruko Oluwa yi


sinu omi na JEHOVAH JARRABBILLAH X 3 sinu omi naa, alaboyun naa, yo ma
mu omina, yo sit un ma fi we ninu re, yo si bi pelu ayo ati alaafia.

11. ETO ADURA IBUKUN: Ki a bu omi sinu ike bucket, ki a pe oruko yi ni kete ti a
ba ti ka Ps naa tan sinu omi naa, Ps 121 x 3, a o pe oruko yi naa
ELLIMMIRRATTAJI, bakana a o tun ka Ps 131 x 3, a o si ma pe oruko yi ni kete ti
a ba ti ka Ps naa tan, ELLIJJARRABBOWAH, a o si tun ka Ps 20 x 3, a o si tun
pe oruko yi ni kete ti a ti ka Ps na ELLIRRABINAH a o si gbadura sinu omi naa, a
o wa lo fi we, e je ki a tera mo ni sise a o si di eni ibukun.

12. ETO ADURA IBUKUN: A o ko Ps yi sinu parchment paper, Ps 72, a o wa ko


oruko yi si abe Ps naa nigba 21 x, AKEMOKEHA JAH, ZERRO ZERROYYE 21 X,
ao si da ina sun iwe naa, a o wa ko eru iwe naa sinu Olive oil tabi bintu, a o si ya
si mimo pelu Ps 21, a o tan imole kan fun.

13. ETO ADURA IBUKUN: A o ya Ami Aworan Agbelebu meta si ara parchment
paper, a o si ko Ps 119: 17-24, Jh 17: 24-26, a o si ko oruko yi si abe re AKEMO
KEHAJJAH ZERRO ZERROYYE, ni 21 x, s o dana sun iwe na, a o wa ko eru re
sinu Olive oil, a o da sasorebia kan sinu re, a o gbadura si a o maa fi pa ara wa,
a o si ri ibukun Olorun.

14. ETO ADURA FUN ISEGUN OTA: Ti awon ota ba dide ogun si o, iwo ma beru, iwo
gba awe ni ojo naa, ki a si gbadura ni aro, osan ati ni irole, ki a si ka Ps 10 x 1, ki
osi pe oruko Oluwa yi nigba meje, JARATIA, AJAJA MOMIN x 7, ki osi gbadura
fun isegun, iwo yo si ri isegun.

15. ETO ADURA FUN IWOSAN: Ka Ps 18 x 3 si ara ara eniti ara re ko ya, ki osi pe
oruko yi si ara re pelu , ni ekan pere ELI-LAJA X 1 ki o si gbadun iwosan fun, ara
re yo si ya. Odaju.

16. ETO ADURA FUN IKO: A o pe oruko yi sinu omi pelu ki a ka Ps yi ELILAJA X 7,
a o ka Ps 7 sinu omi, eni na yo ma mu omi na deedee, yo si ma fi we pelu.

17. ETO ADURA TI EMI ESU BA NYO OMODE LENU: A o gba epo pupo, ti o ba ti
din dada, ti o ba tutu, a o da kerosene die si, ao po eyin mo dada, a o wa ka Ps 10
nigba meji sinu re, a o si pe oruko yi si ni igba mejo, ELILOLA X 8, ki a si ma fun
omo na mu diedie, ki a si fun fi pa lara.

18. ETO ADURA FUN ETI TI KO GBORAN DADA (TI ETI NYO LENU): Omi igi ogede
ti a ti be sile, ti o ti jera, a o mu die ninu re, a o da petrol die si, a po eyin eyo kan
mo, a o fi etui bon die si pelu, a o wa ka Ps 16 x 3, a o wa pe oruko yi si ELIALIA
X 50, a o wa kan diedie sinu eti naa a o si ma fi pe ayika eti naa, eti naa yo
gbadun.

19. ETO ADURA FUN ASEYORI NINU IDANWO: A o wa omi kanga tabi omi ero, a o fi
se eyin eyo kan je, eyikeyi eyin la le lo, a o wa omi ireke sinu omi naa, a o ka Ps
28, 8, 4, sinu omi naa, a o si pe oruko yi sinu re, ELIALARO FAFAJA X 16, a o si
gbadura fun aabo ati imo ati oye sinu re, a o gbe kana, a o se eyin naa, ti o ba
jina, a o tun ka Ps naa si ati oruko Oluwa naa, leyin ti a ba bo epo re, a o je eyin
naa, a o si fi omi ti a fi se eyin naa we, o daju abo yoo wa lori eni naa, yo si se
aseyori.
20. ETO IBUKUN LORI ISE ENIYAN: Ni aro kutukutu ojo aje ti nse Monday, a o ka
Ps 41 x 1, a o si pe oruko mimo yi ELI, ELI-ELIHAHA-HAH nigba mejo a o si
gbadura ibukun lori ise wa, ki a to jade.

21. ETO ADURA ABO LOWO JAMBA MOTOR: Ti o ba fe rin rin ajo, ka PS yi 102: 4-
18, ki o sip e oruko mimo yi OLITARA – KAJAH X 14, ki osi gbadura fun abo,
boya lori oko oju omi tabi ti ofurufu, tabi ti oko ile, abo yo si daju

22. ETO ADURA LORI ISEGUN LORI ISE: A o pon omi odo ti on san ni aro kutukutu
a o ka iwe Deut 27: 1-12 sinu omi na a o sip e oruko mimo yim AJALA, AJALA,
AJALOLA x 8, leyin naa a o wa lo we ni ikorita meta ni akoko ti o ba rowa lorun, a
o si ni segun.

23. ETO ADURA ISEGUN LOWO EMI OKUNKUN TI O NYO IJO OLORUN LENU: A o
tan imole merin si igun ile kan kan, a o tan ikan si arin, a o wa ka Ps yi, Ps 35 x
3, Isaiah 47 x 3, Nahumu 3 x 3, a o w ape oruko mimo yi BAIBATARA HUBIJAH,
ELOI-JAH, ASDAGOGI, ELBARA JAH HULLAHA x 7 leyin na a o gbadura fun
isegun gbogbo awon emi Okunkun ti o nyo ijo lenu, ki o pare.

24. ETO ADURA FUN ENITI O SALO, TABI TI WON JI GBE: A o gbe ile die ni enu
ona ile, a o ka Ps 126 nigba meje ti o ba je Obinrin, sugbon ti o ba je Okunrin a o
ka nigba mesan, a o pe oruko mimo yi sinu iho na, JEHOVAH BANUBA,
TABUBIHI, BAHUOO, ao si se be pe ojo meje ti o ba je Obinrin, sugbon fun
Okunrin a o se fun ojo mesan, eni naa yo pada wale ni kete ti o ba tide, eje ki a di
koto naa,

25. ETO ADURA FUN ISEGUN LORI AWON OTA: A o ra packet imole kan, a o tan
gbogbo re kale, ao ka Ps 84 x 7, a o tan abela naa yipo ara wa, a o pe oruko mimo
yi, BAPA BAPAJIH x 10, a o wa bu iyo die sinu ile, a o wa fi owo (naira) kan si ori
iyo naa, ti imole naa ba ti jo tan, a o lo fi owo naa tore fun onibara, ki o si da iyo
naa nu, o daju eni naa yo ni isegun

26. ETO ADURA ISEGUN EMI IBERU: Fun enikeni ti eru ma nba tabi aya re ma n
ja, e bu omi sinu bucket, omi ti o to lati we, ki e wa ju irin kekere kan sinu omi
naa, ki e wa ka Ps 27 x 3, sinu omi naa, ki e pe oruko Oluwa yi, ELI ELI ALOLA x
4, ki e mu ninu omi naa, esi fi die pa aya yin, ki ewa fi eyi ti oku lowe, e lo se eto
naa fun bi ojo meta tabi jubelo, eni naa yio si segun emi eru naa.

27. ETO ADURA OKA TI O MA NFARAHAN LORI AWON OMO IKOKO (NEW BORN BABY):
E bu omi die sinu ike kan, ki e ka Ps 2 sinu omi naa, ki e fi we omo naa, bakanaa
ki won tun ka sinu olive oil pelu kahun die alomu blue, ki e pe oruko yi sinu omi
ati ororo naa, HURATALA LAKAJA x 10, ki e fi ororo na pa omo na lara ati lori
isegun yoo je tire.
28. ETO ADURA LATI FO INU OBINRIN: A o wa ori, ororo ti a n fi se obe, kerosene
die ati alomu funfun, a o da gbogbo re papo, ti yoo kuna, a o ka Ps 50 x 6 sinu re
a o pe oruko mimo yi si ELI ALA GOD x 26, a o si ya si mimo, s o tan abela
funfun meta si idi omi naa.

29. ETO ADURA FUN OMO TI KO TETE RIN: A o pon omi odo ti o nsan sinu ike a o
fi imo ope eyo mewa sinu omi naa a o si ka iwe Owe: 9: 1-titi de ipari a o si pe
oruko mimo yi si ALALA, HO, HO, HO, HA, HA, HA, ELI SAMUEL x 100, a o si
tan imole mewa yi omi naa tan, a o si gbadura si omi naa, leyin adura, a o yo imo
oje naa kuro, omo naa yo ma mu omi naa, yo si tun ma fi we.

30. IPARA FUN OMO TI KO TETE RIN: A o wa ori, adi agbon, olive oil ati kerosene
die ati ororo malu die, a o da gbogbo re papo, a o ka iwe Gen 2: 1-4 sinu re, a o
pe oruko mi mo yi si ELI SAMUEL x 84 a o maa fi pa lara, yoo si ma mu die ninu
re.

31. ETO ADURA FUN OBINRIN TI AYE GBE OKUTA SINU RE TABI TI O NI IJU: A
o bu omi sinu ike bucket funfun, a o fi irin kekere kan sinu re, a o tan abela meta
yi ka, a o ka Ps 24 x 7, a o sip e oruko mimo yi si ALOLA LAJAKA KARARA x 7 ki
eni yen mu die ninu omi naa, ki o si fi eyiti oku we, se be fun ojo meje, yo ri
iwosan.

32. ETO ORORO ADURA FUN OBINRIN TI OKUTA WA NINU AYE RE TABI IJU:
Ororo jije, a o fo eyin kan sinu re, alomu funfun ati blue, a o lo, a o da sinu ororo
naa, a o ka Ps yi si JAH ELI ALA x 21, eni naa yo maa mu, yo si maa fi pa ikun
re.

33. ETO ADURA ILE GBIGBONA (Small Pox): A o ka Ps 84 x 2, 10 x 2, sinu omi fun
eni naa, a o si pe oruko Oluwa yi si ALOJAH, ALOJAH, ALOJAH x 21, ki eni
naa si fi we.

34. ETO ADURA FUN ENITI O N BI ABIKU OMO: A o bu omi sinu ike bucket
tuntun, a o fi imo eyo meta sinu re, a o tan imole meje sinu omi naa, ki omi naa
le pe nigbati o ba jo de ibitii omi naa wa. A o si pe oruko Oluwa yi sinu omi na
ELILAH ELILAH EULAH, ALOLAH, ALOLAH, ALOLAH, ELOLALAH, ELOLALAH,
ELOIALAH x 62, Obinrin naa yo si fi omi na wa ni ikorita meta ni akoko ti o ba
rorun fun o daju ko ni bi abiku omo mo.

35. ORORO ADURA FUN OBINRIN TI O BI ABIKU OMO: Omi agbon, adin agbon,
kahun die, alomu blue, ki lo papo mo ara won, ki a wa pe oruko yi si ki a sit un
ka Ps naa si eyiti o wa loke yii.

36. ETO ADURA FUN INARUN: E bu omi sinu ike bucket, ki e tan imole meta yi omi
naa ka, ki e ka Ps 9 x 1 sinu omi naa, ki e si pe oruko mimo yii, SAFATAYAH
SAFATAYAH x 7 ki e si fi omi naa we, ki e si se be dada leralera, ki eni naa wa
adin agbon pelu ori ki o po papo, ki o ka Ps 23 x 7, sinu re, pelu oruko ti o wa
loke yii, ki o ma mu ki o ma fi para.

37. ETO ADURA FUN INU RIRUN: A o ka Ps yii sinu omi Ps 3 x 1, Ps 1 x 1, Ps 2 x1


sinu omi a o pe oruko mimo yii si WALOLA ASABATA JAH x 84, ki eni na fi we

38. BAKANNA KI O SE ELEYI FUN MIMU: A o gba epo pupa, kahun die, ati iyo die a
o po eyin kan mo, a o sip e oruko ti owa loke yi si pelu Ps naa, ki o maa mu
diedie.

39. ETO ADURA FUN INU TI O WU: A o wa omi odo ti on san sinu ike bucket
tuntun, a o fi imo ope odindi kan sinu re, bakana a o tun wa imo ope ti o sese
nyo, ti ko ti dagba pupo, e yo meta pere sinu omi naa, a o si tan imole mesan yi
omi naa ka, a o kaPs 20 nigba ogoji (40x) a o si pe oruko mimo yi si ELI SAFATAN
62 x 1, a o se be fun ojo mesan, leyin ojo kesan yo si fi omi naa we.

40. ORORO ADURA FUN ENITI INU RE WU: A o gba epo pupa a o da po pelu adi
agbon, a o si fi ito maluu die si pelu ori, a o da gbogbo re papo, a o wa ka Ps 20 x
40 sinu re, pelu oruko mimo yi (ELISAFATAN 62 x) ki eni naa ma mu die, ki o si
ma fi para, ki o si ma ta die sinu omi we ti o ba ti tan, ki e tun omiran se fun.

41. ETO ADURA ESE TO WU LAINI IFARAPA: Omi odo ti o san, a o bu sinu bucket
titun , a o tan imole mejo yi ka ike omi naa, a o ka Ps 4 x 3, Ps 20 x 3, Ps 19 x 3,
ti a ba tin n pari Ps kokan ni a o ma pe oruko mimo yi, ELIJAH SOFO ki a si fi
omi naa we, a o si se be fun ojo meta.

42. ORORO ADURA FUN ENITI ESE RE WU: A o wa ori a o pa po pelu eyin pepeye, a
o fi engine oil die si, adin agbon ati kahun die si, a o ka Ps ti o wa loke yi si pelu
oruko Oluwa naa.

43. ETO ADURA FUN OBINRIN TI A DE OYUN MO NINU: A o bu omi sinu ike
tuntun, a o fi okuta wewe meta sinu re, a o ka Ps 27, 28, 29 x 16 a o si pe oruko
Oluwa yi si ELILARORA X 12 a o si gbadura si, ki eni naa ma mu omi naa, ki o
sit un ma fi we, yio bi oyun na ni irorun

44. ETO ADURA FUN ETE: A o wa ra omi okun ati osa, pelu omi adagun a o da papo
ao ka Ps 109 x 1, 102 x 1, 100 x 1 sinu omi naa, a o si pe oruko Oluwa yi sinu
omi ELIKAHAJAH x 80, fun mimu ati wiwe.

45. ORORO ADURA FUN ETE: A o wa eja oni pepa lara, gbigbe, a o lo po pelu ori, a o
fi ororo malu po papo pelu eyin kan a o wa ka Ps 109 x 1, 102 x 1, 100 x 1 sinu
re, a o si pe oruko yi si ELILAHAJAH x 80 eni naa yo ma mu, yo si ma fi para.
46. ETO ADURA FUN EFORI OMODE: A o wa ike bucket titun, a o ka Ps yi sinu re,
Ps 41 x 3, 21 x 3, 4 x 3, a o si pe oruko Oluwa yi si ELIELA X 66 omo naa yo ma
mu yo si ma fi we pelu.

47. ETO ADURA AISAN TI O LAGBARA: A o bu omi sinu ike bucket titun, a o tan
imole mejila yika bucket oni naa, a o ka Ps 21 x 20, sinu omi naa a o si pe oruko
Oluwa yi sinu omi naa DABOLA ELILAJAH, eni naa yo ma mu omi naa, yo si tun
ma fi we.

48. ORORO ADURA FUN AISAN TI O LAGBARA: Adin agbon pelu ori a o po papo a o
wa ka Ps yi si 21 x 20, a o si tun pe oruko mimo yi si, DABOLA ELILAJAH ki eni
naa maa mu, ki o si maa fi para re.

49. ETO ADURA GIRI OMODE ATI AGBA: A o bu omi sinu bucket, a o tan imole
meta yika, a o ka Ps 1 sinu omi na a o pe oruko Oluwa yo si HELA HOLA X 84
sinu omi naa, ki eni naa fi omi na we, ki o si mu ninu re, bakana ki a ka si ni ori
pelu eni naa yoo si san.

50. ORORO ADURA FUN GIRI OMODE ATI AGBA: A o wa ogogoro, a o lo kahun die
si, pelu alomu blue, a o po papo, a o ka Ps 1 x 1, nigba kan sinu re, a o pe oruko
Oluwa yi si HELA HOLAX 81, ki eni naa ma mu, ki o si ma fi pa ara re
nigbagbogbo.

51. ETO ADURA FUN ENITI ONI ARUN OPOLO: A o bu omi sinu bucket tuntun, a o
tan imole 21 yika bucket naa, a o ka Gen 1: 1 titi de ipari, Eks 2: 1 titi de ipari,
Rev 4, Jh 1: 1-5, a o si pe oruko mimo yi si, ELI ALAH ASAROTAH X 84, ki eni na
ma mu omi na, ki o si ma fi we, ti omi na ba ti tan ki e tun se omiran.

52. ORORO ADURA FUN ENITI ONI ARUN OPOLO: A o wa ororor eran aguntan ati
ororo eran malu, pelu ori ati omi agbon ati emu mimu, pelu ororo jije, a o pelu
eyin adie kan mo, a o wa po gbogbo re papo, a o wa ka bibeli yi sinu re, Gen 1: 1
titi de ipari, Eks 2: 1 titi de ipari, Rev 4, Jh 1: 1-5, a o tun pe oruko mimo yi si,
ELI ALAH ASAROTAH x 84 ki eni naa ma mu, ki osi ma fi para, iyanu yo si sele.

53. ETO ADURA OSE ISEGUN LORI AWON AJE: A o ra ose dudu tabi waiti soap, to
ba je white, a o gun dada, a o wa da bintu kan sinu re, a o po papo, a o wa ka Ps
wonyi si nigba meta ni ojumo na fun ojo meje, Ps 3 x 3, 35 x 3, 30 x 3, 59 x 3, 83
x 3, 91 x 3, 103 x 3, 30 x 3, 40 x 3, 104 x 3, Isaiah 35 x 3, leyin ojo keje, a o ma
bu we, odi dandan, ki awon aje ma sa fun wa.

54. ETO ADURA FUN ISEGUN ORI BURUKU ATI IJAKULE: A o wa bucket titun,
omi okun ati omi osa, eyiti o to we, a o ka Ps yi si, Ps 12, 21, 10, 13, 18, 19, 20,
27 x 1 a o ka gbogbo re ni ekan, a o bu iyo die sinu re, pelu kafura pelebe eyo
kan, a o ra ose ati kahin kan tutu a o tun ka si inu ose naa ati kahin kahin, a o
tan imole kan fun iyasimimo na, a o si se eto na fun ojo meji tabi meta, a o pe
oruko Oluwa yi si nigba meje JAH SAHATA x 7, a o wa gbe koto ko jin die, a o wa
we iwe na ninu koto naa, a o lo ose ati kahunkahun naa, ti a ba ti we tan, a o so
ose ti o kun sinu koto na, ati kahunkahun a o wa di koto naa a o nilo bucket naa
mo, ona yo si fun wa, a o si ri ona abayo.

55. ETO ADURA FUN OBINRIN TI IBIMO RE LEWU: A o pe oruko Oluwa yi si ori
Obinrin na o si di dandan, ki o bi omo naa, irora yo si ka kuro BABIHUBA
AHAJAH BAHABIHUBA JAHULLAH X 21.

56. ETO ADURA FUN IFERAN OBINRIN TABI OKUNRIN: Eniti o fe se eto naa, yo fi
enu re bu omi sinu igo kan, igo na le ma kun, a o wa bu omi miiran sinu abo
kan, lati le jeki igo naa kun, a o wa fo oju wa sinu omi na nigba meje, bakan na a
o wa fo abiya wa sinu omi na nigba meje, iyen omi to wa ninu abo, kise tinu igo ti
a fie nu bu o, a o wa da papo sinu igo na, lati le jeki omi inu igo na kun leyin na,
a o wa daruko eni naa, ti o ba je Okunrin lo fe lo fun Obinrin yo daruko eni na
nigba 21, yo tun pe EFA x 21, ti o ba je Obinrin ni o fe, yo daruko Okunrin na ni
21 x time, yo tun pe ADAMU x 21 yo wa ka iwe Ruth 1: 16-17 a o si daruko eni
naa, nigbati a ban ka iwe Ruth, a o tun ka Ps 133, Jh 1: 1-4, Solomon 3: 1 titi de
ipari a o si se eto na ni oru, ti a ba ti pari re, a o wa fun eni na mu diedie, eni na
yo si bere si nife re dada.

57. ETO ADURA FUN ORO EJO TABI AKEKE: Ti ejo ba bu eniyan je tabi nkan oloro
miiran, a o pe oruko Oluwa yi si inu omi gbigbona tabi erupe ile, a o ka Ps 24 x 4,
sinu re a si pe oruko yi si, nigba mesan, SELIDINMI SASHARA TABBIH X 9, a o si
gbadura si, a o wa gbe si oju ibiti oro na ti wole, ibe ni a o ti ka Ps naa, ati oruko
naa a o ni ki oro ejo na jade, o daju yio jade. A tun le lo fun ofa ti won ba ta fun
eniyan.

58. ETO ADURA FUN ALAKALA: A o toju eyin adie kan, ni ale, a o ka Ps 27 senu
eyin naa, nigba meta a o tun ka lasan, ki a to losun, ti ile ba mo, a o fo eyin na
sinu ike kan, a o wa bu isebe die sinu re, a o po papo, a o tun ka Ps 27 sinu re
nigba meta, a o wa ro papo a o fi ika kan a o fi pa iho imu wa mejeeji, bakanna a
o tun fi pa iho eti wa mejeji a o wa da eyin ti o kun nu a o si gbadura , o tan.

59. ETO ADURA LATI BORI AWON EMI ESU GBOGBO ATI EMI AIMO: A o ma ka
Ps yi ni ojojumo fun adura bakana ni a o ma ka sinu omi iwe wa ni ekan tabi
jubelo sinu omi iwe wa laarin ose, a o si se eto na fun osu meta gbako ti a ba le
se, o daju ko si emi Okunkun ti yoo yo wa lenu mo, a o si ni agbara lati bori awon
emi Okunkun gbogbo. Ti a ba ni ore-ofe ki a ma tan abela yi fi se adura naa,
abela dudu meji, abele pupa eyo kan, abela orange kan, purple kan, pink eyo kan
ati abela funfun meta, ki a si ma ka Ps yi sinu omi naa pelu adura, Ps 71 x 1, Ps
130 x 7, Ps 137 x 3, Ps 53 x 1, Ps 54 x 1, Ps 55 x 1 ti o ba se eto na fun osu
meta, iwo yo ni isegun gbogbo awon emi Okunkun, iwo yo si di alagbara lori
awon emi Okunkun gbogbo, je ki o pe osu meta gbako.
60. ETO ADURA FUN EWO (BOIL): A o bu omi sinu bucket kan, a o fi okuta wewe
meta sinu re, a o wa ka Ps 3 nigba meta sinu omi naa, bakana a o po eyin mo
ororo olive oil, a o po papo dada a o si ma fi pa oju re, a o fi omi naa we, a o si ni
isegun lori ewo naa.

61. ETO ADURA IGBESAN LARA OTA: Ti ota ba nfi iya je o lainidi tabi won koriira
re pelu ni ayika re ka Ps 51 x 1, 54 x 1, 55 x 1 ki o si pe oruko mimo yi ni 21
times, OMIMIHIMI SABADINAH loju ese ni Oluwa yo ja funo yo si gbesan kiakia

62. ETO ADURA LATI TU EJO KA: Ki woli ti o fe se eto naa gbawe ojo meta,
bakanna eniti o ni ejo na, ki o gbawee ojo meta, ti ejo na ba ku ojo meta, ki a lo
ra agbon ti o ni omi ninu dada, a o tan imole meta yi agbon na ka, a o ka Ps 51 x
7, 13 x7, 77 x 7, 83 x 7, 110 x 7, 35 x 3, 148 x 3, a o pe HOLY MICHAEL a o koju
EAST a o pe HOLY GABRIEL a o koju si WEST a o pe HOLY RAPHAEL, a o koju si
NORTH, a o pe HOLY URIEL ROLLER, a o koju si SOUTH, a o tun pe oruko mimo
yi gbadura nigba meje ni a o pe oruko na JEHOVAH ATURAKAJA X 7 a o so wipe
ejo ti o wa niwaju --------------- omo ------------ ni ile ejo ------------- ki Oluwa tu ka
a o tun je oruko yi nigba meje WOMWOMWOBAH x 7, a o si gbaura si agbon na
dada wipe ni ojo ti agbon bi fi ori so apata ni o ma tuka, a o wa fo agbon naa mo
okuta a le jo wa okuta nla sile, tabi ki a le fo mo apata, agbon yen gbodo fo ni
ekan o, ki a fi agbara fo mo apata tabi okuta nla, e je ki a se eto naa saaju ojo ti
a o lo si kootu, isegun daju. Ti won ba sun ejo naa siwaju ki a tun eto naa se ni
ojo meta saaju ojo naa.

63. ETO ADURA ISEGUN OUNJE JIJE LOJU ALA: A o bu omi sinu ike bucket
bakan na ni a o ra ororo olive oil a o ka iwe mimo yi sinu re, Lef 26: 7 x 7 nigba
meje, a o tun ka iwe Isaiah 8: 9-10 nigba kan, a o tun pe (JAH-TEIAH x 3) a o tun
ka Ps 3:5-7 nigba kan, a o tun pe JAH KOROKOJI x 1 a o tun ka Ps 68: 1-2 nigba
kan a o tun pe KEUJAH x 3, a o tun pe JAH HADDUM x 51 times, a o tun ka
Matt 10: 2-4, a o tun pe JEHOSHAFAHTII leyin naa, a o wa gbadura si omi naa
ati ororo naa, a o fi omi naa we, a o si ma mu ororo na die die a o sit un ma fi
para.

64. ETO ADURA LATI DA OJO DURO: A o gbaawe ni ojo ti aba fe se eto naa, a o pe
SOSAL nigba meje a o tun pe JAH JEHOVAH x 7 si igun EAST, a o tun pe HOLY
MICHAEL X 7, si igun WEST a o tun pe DONIJEHOSI x 7 si igun SOUTH ati
NORTH, leyin naa a o pe oruko yi JAH HE, a o si ka Ps 121 si igun EAST, WEST,
SOUTH, NORTH, leyin na a o wa pase wipe ki angeli ti o ni kokoro ilekun ojo ki o
ti, ni akoko yi, ki ojo ma se ba ohun ti e fe se je, o daju, ese eto na ni oku ojo
meta tabi ojo meta saaju ohun ti e fe se, o daju.

65. ETO ADURA FUN OJA TITA: A o bu omi sinu igo tuntun kan, a o si tan abela
onirawo a o fi yi igo omi naa ka, a o ka Ps 12 x 7, 114 x 7, a o sipe oruko Oluwa
yi si ELLI X 7, JEHOVAH SHAMA nigba meje a o wa gbadura si a o ma fi omi naa
won ile itaja wa, ati oja wa bakan na a o ma fi fo owo wa.

66. ETO ADURA IWOSAN GBOGBO ARUN: Eto adura yi lagbara lopolopo, ti ko ba ti
ni ni owo aye ninu, ko si arun to ba pade ninu aye eniyan, ti ko ni wo san, a o ka
Ps 91 x 11, Ps 24 x 3, Ps 68 x 7 sinu omi naa, a o wa pe oruko Oluwa yi sinu omi
naa ELOHIM ADONAI ZABAOTH SHADDAI x 7 a o pe gbogbo re nigba meje a o
maa mu omi yen ni owuro kutukutu ati ni ale, a o bu die sinu om iwe wa, o daju
a o yin Olorun

67. ETO ADURA FUN EGBO ADAJINA: Ti aye ba fi egbo adajina ba o ja tabi eniti
osun mo o, jowo se eto yii fun, iyanu si sile niyen, ka eto na sinu omi ati ose pelu
ororo a o ka Ps 146 x 3, 91 x 3 ki a pe oruko yi sinu re nigba meta a o tete pe
oruko naa saaju kika Ps wonyii. Oruko naa ni JEHOVAH KALABIRI KIHORAH x 3
a o tun pe si oju ogbe naa a o tun pe sinu ose naa bakanna sinu ororo naa, ki e
wa lo kafura pelebe mo ori, ki eni naa ma le ori naa mo oju egbo naa, ki o maa
mu omi naa, ki o si ma fi ororo na para ki o si ma mu ninu re, a le se be fun ni
ojo meji leralera, ki a ma pe oruko na si oju egbo na ati kika Ps naa. O daju.

68. ETO IWE ADURA ITUWO AWON AGBA ATI ASINA: Ewe lapalapa ti ojo pupa ati
funfun, ewe ajeobale ti ojo, a o wa fi eyin ibile ti ko ti di obu kan si isale pot wa, ti
o gba oni toto we, a o ko ewe lapalapa pupa le, leyin na a o ko ewe ajeobale le, a o
wa ko ti lapalapa funfun le lori a o se ti o ba ti jina a o da sinu ike iwe, ti o ba ti
tutu dada a o wa ka Ps 35 x 7 sinu re a o si so eyin naa sinu re pelu a o wa fi omi
naa lasan san ara wa, ti a ba ti we tan a o je eyin naa a o da epo eyin naa nu si
oju ona titi a o se adura ki a to jade kuro ni ile iwe. O daju ona yoo si aye yoo si
tuwo lara wa, a le se eto naa fun bi igba meta ninu osu.

69. ETO OSE ADURA ITUWO AGBA ATI ASINA: A o wa eso ido merindinlogun (16)
bakana a o wa eso werenjeje merindinlogun (16) a o gun won lori olota papo, a o
wa fi ose ti o to we ni eekan po papo, a o wa ka Ps 68 x 3 sinu ose naa, ti o ba di
ale, ti a o ni jade mo, a o wa we ose naa a o po adin die pelu ori ati epo pupa po
mo ara won, awon nkan wonyi ni a o koko fi para, ki a to we iwe naa. Ise yi dara
pupo, ti a ba sun o sese ki a lala isegun tabi ki ala naa ma ni itumo, sugbon a o
ni isegun a le se eto naa fun igba meta ninu osu naa.

70. ETO ADURA FUN OWU ALANTAKUN: Ito ti a to ni idaji, a o to si ibi kan, a o wa
fi owo osi lu ito naa, a o wa fi pa ori wa, a o tun fi owo na tun lu, a o fi owo na pa
oju wa, a o fi sile fun ni iseju mewaa, leyin naa a o fi ose adura we, a o ka Ps 68 x
7, 40 x 7, 18 x 7 sinu ose iwe funfun, ose yi ni a o ge die nibe a o wa fi we iwe
naa, a le se be fun ojo meje, a o nisegun, owu alantakun ko ni kan wa mo. O
daju.
71. ETO ADURA AWORO: A o wa agbon ti o tobi dada, a o jo omi inu re danu a o wa
jo ori owawa ti o pe dada pelu atare aja eyo kan, a o wad a sinu agbon naa a o to
ito (urine) idaji sinu ike kan, a o tun ito enu idaji sinu re a o po papo, a o wa ro
sinu agbon na, a o wa se adura bi ase fe ki o ri fun wa, a o fi nkan de oju re, a o
wa kan abela si oju re dada, a o wa lori mole si enu ona shop tabi arin shop a o
ko ibiti a dalu si oke ninu koto na.

72. ETO ADURA OSE IBUKUN ATI ASINA: A o ra orisi ose funfun meta, a o gun
gbogbo re papo mo ara won, a o ko sinu ike white a o po oyin gidi mo pelu omi
ireke, omi okun ati osa die pelu lofinda six flower a o ko sinu ike funfun a o wa
tan imole mesan yi ka ike naa a o ka Ps 119 x 1, 128 x 1, 4 x1, 24 x 1 a o
gbadura ibukun ati ki ona ki osi sile fun wa, ti imole naa ba ti jo tan, a o de ose
naa, a o ma fi we ni ojo MONDAY/WEDNESDAY Obinrin ti o n se ikan osu ko
gbodo fi owo kan.

73. ETO OSE ADURA FUN ISEGUN AWON AJE: Ewe okuku, epo obo, igbin kan, a o
wa gun papo mo se ti a ba ti pari gigun re, a o si ya si mimo pelu Ps 35 x 7, 40
x7, 68 x 7, ti a ba fe we ose naa ni ona ti o lagbara, lati tete segun awon aye a o
we ose naa ninu apere ti ide re ti jade a o duro ninu re, we ose yen ni ago kan oru
a o ra kahunkahun tuntun kan a o we fun ojo meta pere, awon aye yo tun wo
kuro lara wa, a tun le we lasan, lailo apere bakana o le fun eniyan miiran lo, ki
won we ninu re eto naa dara gidigidi gan ni sugbon ti o ba fe we ni ago kan oru
ma nu omi ti o wa lara re.

IKILO PATAKI
E jowo gbogbo eni ti o ni anfaani lati se alabapade iwe owo yin yi, mo be wa nitori
Olorun e ma gbiyanju lati se eda iwe yi fun eniyan tabi ki e se atunko re tabi ki e lo te
sita laigba ase lowo emi ti mo ko iwe yii ti a ba ri enikeni ti o tapa si ase yii, irufe eni be
yo ri awon ewu meta ti o je edidi iwe yi. Ewu akoko ni wipe yoo ma sise sinu ajadi
apere ni, ewu keji ni wipe awon ogun orun yo tilekun awon ona gbogbo mo, ewu iketa
ni wipe aisan ti ko ni se won yoo je ti irufe eni na. Jowo ma se gbiyanu re lati tun iwe
naa ko sita rara, ma se s e eda re fun eniyan lai gba ase lowo olukowe naa.

Nitori iwe owo re yii, anfaani nla ni ori ti o fi te o lowo, awon omo Woli ti o keko Woli ti
o ti jiya fun eko ni owa fun, sugbon mo fi aye ati ore-ofe fun gbogbo awon omo Woli, lati
tete ni iwe yii. Jowo ma se si ore ofe naa lo, yo dara fun wa o (Amin). Ijoba Olorun ko ni
bo lowo wa, ogun esu, ogun ese, ati ogun eniyan mimo ko ni bori wa o (Amin).

Ti o ba ni ibere Kankan, o le pe mi (08185386093, 08091198826) tabi ki o ba mi soro


lori Email agbaramiko@gmail.com, or prophetmichealagbaramiko@yahoo.com or
facebook.
EGBOGI FUN IWOSAN
Olorun ni o da ewe ati egbo, o si da fun iwosan aye awa ti a je omo eniyan, opolopo
awon eniyan ni won sa seyin fun lilo ewe ati egbo, won nigbagbo wipe awon babalawo
ni o ma nlo won. Awon miiran gba wipe ti o ba lo egbo, tabi ewe won ni o ti di babalawo
niyen, leyi ti ko si ri be rara. Niwon igbati an lo tablet ogun awon oyinbo, Olorun lo fun
wa ni ore ofe lati ni ki awon ewe yii ma hu jade fun iwulo igbe aye eniyan. Sugbon
eniyan ko gbodo lo lati fi se ika rara. Ninu iwe Genesisi Olorun so wipe eniyan nilo re,
ati wipe yo wulo fun eniyan o si da eweko ati opolopo igi, saaju ki o to da eniyan.
Gen 1: 11-12 ti o ba iwe Ezk 47: 12. Nitori idi eyi ki se ese ti o ba lo agbo, tabi ti o lo
awon egbogi fun iwosan ara re, jowo ma se lo fun ipalara awon miiran yoo dara fun o
(Amin).

1. EGBOGI FUN ENITI O N BI ABIKU: Eru Alamo, ori eran owawa, a o se papo, ti o
ba jina tan, a o ya si mi mo pelu Ps 24 x 3, 18 x 1, eni naa yo ma mu, nigbati
oyun naa ba ti pe osu keje, cup kan ni aro, a o se eto naa nigbati oyun ba ti pe
osu meje, yo maa mu titi yoo fi bi omo, ti o bas a, a o tun se omiran.

2. EGBOGI KI IDAKOLE MA LE MU ENIYAN: Egbo igi osunsun, egbo igi idi apata,
egbo aika, atare 1, a o gun gbogbo re papo, a o sag be a o maa fi mu eko gbigbona
ni owuro a o ya si mimo ki ato maa lo pelu Ps 23 x 1, 40 x 1.

3. EGBOGI FUN AISAN AIPERI: Epo igi aye, kahun, a o gun papo sinu omi osan
wewe, a o se pelu ase, a o ro pada sinu igo, a o ma mu cup Kankan ni aro ati ale
a o si ya si mimo pelu Ps 24 x 1

4. EGBOGI FUN AKOKORO: Ewe ati egbo gbegi, eru Alamo, ewe taba, a o se, a o
ma di si enu wa fun ni iseju marun, a o si tun ma la enu wa si orun re, ti a ba ti
gbe kana, a o ya si mimo pelu Ps 24 x 1, 40 x 1.

5. EGBOGI FUN AISAN IPAKE: A o wa iye eye kanakana, a o jo a o da sinu epo, a o


ma la diedie a o si ya si mimo pelu Ps 12 x 1, 14 x 1, igi ti won fi sin eja, a o jo, a
o ma la lasan, a o si ya si mimo pelu Ps 18 x 1.

6. EGBOGI FUN IDABOBO LOWO OFA: Egun araba, egun ara igi ota, ataire kan, a
o jo papo a o lo etu ibon ti ibile si, a o ma fi mu eko tutu, a o si ya si mimo pelu
Ps 22 x 1.

7. EGBOGI APORO OFA, TABI ORO EJO, ATI NNKAN OLORO MIIRAN: Oka baba,
ori ejo oka, ogede wewe pupa, a o jo won po, a o ma la a o si ma fi pa oju ibe
leyin na a o ya si mimo pelu Ps 18 x 1.

8. EGBOGI FUN ARAN: Ewe agbosa, a o gbo sinu oti, ao mu die die, ni araro, a o ya
si mimo pelu Ps 17 x 1.
9. EGBOGI FUN ARAN AYA: Ako okuta kan, ota inu Iroko, atare eyokan, korofo
eyin adie ibile, a o lo won papo, a o ma lo sibi ijeun omo kekere ni aro, a o si ya si
mimo pelu Ps 109 x 1.

10. EGBOGI FUN ERO ATA SISONI: Eso tagiri kan, oga 1, ewe imi-esu, egbo nabiri,
epo die, ori ati adin, a o wa gun papo mo ose white x 1. A o wa ya si mimo pelu Ps
24 x 1, 91 x 1.

11. EGBOGI FUN ATOSI ELEJE: Ewe imi Esu, a o gbo sinu omi, a o po efun si, a o
maa mu ni aaro ati ale, a o si ya si mimo pelu Ps 44 x 1.

12. EGBOGI FUN ETI TI O NDUN ENIYAN: Kokoko ikandu, a o lo sinu adin, a o ma
kan sinu eti naa ni ale, a o fi owu di mo, ya si mimo pelu Ps 17 x 1. Kokoro
ikandu, egbo igi isin, a o lo won po sinu oyin, a o ma fi ye eyele to si eti naa, a o
si ya si mimo pelu Ps 17 x 1.

13. EGBOGI FUN ARUN EDA: Ewe mesinmesin, orogbo 7, atare odindi 3, e yo, a o
gun won papo, Obinrin naa yo maa fi fo eko mu ni aro titi eda na yoo fi da tan, ya
si mimo pelu Ps 22 x 1.

14. EGBOGI FUN EFORI: Eku asin 1, ewe ajeobale, atare 1, a o lo won po sinu adin
a o si ma fi pa ori naa, a o ya si mimo pelu Ps 26 x 1.

15. EGBOGI FUN EFORI TULU: Ewe agbosa, ao gbo sinu omi, a o maa fi we oju ni
aro ati lale, a o si ya si mimo pelu Ps 18 x 1, 24 x 1

16. EGBOGI FUN IWOSAN ARUN ETE: Egbo awogbarun, etu ibon, oje oro a o gun
won po mo ose, eni naa yo ma fi we nigba gbogbo, a o si ya si mimo pelu Ps 18 x
1, 91 x 1, 34 x 1, 68 x 1.

17. EGBOGI FUN IWOSAN ARUN GEGE ORUN: Eso wowo, erupe ogan ti o wo sinu,
nitumo wipe ti o jin sinu, a o bu a o se pelu eso naa, mimi ni cup kan ni ale ati
owuro, a o si ya si mimo pelu Ps 24 x 3, 18 x 3.

18. EGBOGI FUN AISAN IKO EGBE: Opolo eyo kan, tete abalaye, atare eyo kan, a o
jo won papo, eni na yo ma lo sibi idaji kan ni aro ati lale, a o si ya si mimo pelu
Ps 91 x 1, 44 x 1

19. EGBOGI FUN OMODE TI KO TETE SORO: Ewe ailu, egun orun kanakana, a o
fomi se won papo, a o si ya si mimo pelu Ps 33 x 1, eni na yo si maa mu ni ale.

20. EGBOGI FUN ARUN IROBO (IDI YIYO): Alubosa onisu, baka, oje oro alago, omi
osan wewe a o lo papo a o maa fi pa oju ibe, a o si ya si mimo pelu Ps 91 x 3.

21. EGBOGI FUN OMO TI ON TOSILE: Igbe Adie, Orogbo 1, Atare 1, a o lo on papo,
eniyan naa yo ma la diedie, a o si ya si mimo pelu Ps 23 x 1, 127 x 1, 126 x 1.
23. EGBOGI FUN ARUN KOKORO OMU OBINRIN: Ewe koko pupa, pelu omi osan
wewe, ikode kan, a o fomi se papo, a o wa ka Ps 27 x 3, 18 x 3, 40 x 3 sinu ose
white x 1, a o ma fi we pelu kahunkahun tuntun a o maa fi omi agbo na we.

24. EGBOGI FUN AISAN LAKUREGBE: Epo igi pandoro, orogbo 8, atare 8, ata ijosi,
alubosa onisu kan, kahun, iyo, a o gun gbogbo re papo, a o si sa ti yo gbe, a o ma
bu sinu eko ni sibi kan, eko gbigbona ni aro, ipeta, aidan, egbo ife, egbo lara,
alubosa onisu 1, a o gun won pa po, a o ma fi mu eko ni aro, a o ma bu sibi kan
kan sinu re, a o si ya si mimo pelu Ps 30 x 3, 23 x 1

25. EGBOGI FUN ARAN OKINISA: Epo igi aye, kahun a o gun won po sinu omi osan
wewe moju di ojo keji, ti o ba di ojo keji, a o ma yo omi osan mu, ni Cup kan ni
aro, ti aba ti mu a o jeun titi ago mejila osan a o si ya si mimo pelu 40 x 1, 92 x 1

26. EGBOGI FUN AISAN OGUN ORU ATI WARAPA: Aidan meji, akere 2, epo igi
madunmaro, a o jo won po, a o lo ogede wewe pupa papo m o won, a o wa fie je
aje se je lobe ni owuro kutukutu fun eni ti o ni warapa. A o sig be koto ti yo bi si,
ti o ba fi bi tan, a o di koto naa, a o ya obe na si mimo pelu Ps 21 x 3, 91 x 3, 24
x 1, 109 x 1, 68 x 1. Eru Alamo pelu alomu blue, a o ko si inu ike bucket kan ti o
ni ideri a o ja ewe bomubomu die si, a o wa da omi sinu re, leyin oko keta eni naa
yo ma mu, a o gbe koto kan sile, ti yo bi si, a o ya si mimo pelu Ps 16 x 3, 17 x 1,
10 x 1 fun eni to ma mu.

27. EGBOGI FUN AISAN IKO ASIMA: Koro ibepe to pon, a o ko koro naa sinu ike
kan, a o ka Ps 40 x 3, 18 x 3, 27 x 3, sinu koro naa, a o wa je gbogbo koro naa
tan, a o wa mu osan mimu merin si, leyin naa, a o wa je epo ti o wa ninu awon
osan naa, a o ni je epo re, sugbon ti inu osan naa, a o je mererin tan, iko naa yo
pare lagbara Olorun.

28. EGBOGI FUN AISAN TYPHOID FEVER: Epo igi mangoro, osan wewe marun,
ibepe dudu eyo kan, ope oyinbo ti ko tip on meji, alabukun odindi mefa, a o wa
da gbogbo re papo, a o se lori ina ti o ba jina dada a o ma mu, a o ya si mimo
pelu Ps 18 x 3, 91 x 3, 24 x 3.

29. EGBOGI FUN AISAN STROKE: Egbo osunsun, egbo ipeta, egbo akoko, ero
awonka, a o se gbogbo re papo mo ara won, ti o ba tutu, a o ya si mimo pelu Ps
64 x 3, 24 x 3.

30. EGBOGI FUN EJE RIRU (HIGH BLOOD PRESSURE): Ewe afomo onisana gbigbe,
a o lo yo kuna dada, a o ma bu sibi ijeun meji sinu tea elewe (Top tea) a o fi sile
fun bi iseju marun, leyin naa a o se a o si gbe mu, a o si ma mu ni aro ati ale, fun
odindi ose meji tabi titi aisan naa yo fi pora, a o si ma ya si mimo pelu Ps 43 x 1,
40 x 1, 104 x 1, 109 x 1.
31. EGBOGI FUN IKO TUBERCULOSIS: A o lo ge ite ogede agbagba, a o lasi meje ti o
ba je Obinrin, ti o ba je Okunrin, a o ge si mesan, a o wa fi omidun se lagbo, a o fi
kahun bilala si pelu eni naa yo maa mu ni aro yo si ma fi we pelu kika Ps yi 18 x
3, 40 x 3.

32. EGBOGI FUN AYA JIJA: Ewe aluki tutu, a o re somi, a o si maa mu leyin ojo
keta, yasi mimo pelu Ps 24 x 3, 17 x 3.

33. EGBOGI LATI MU OJU MOLE KEDERE: Egbo akomu, a o re sinu omi, a o ma
mu leyin ojo keta, ya si mim pelu Ps 24 x 1, 109 x 1

34. EGBOGI FUN AISAN JEJERE (CANCER): Egbo ifan, oju oro, ekuro oju ona, eso
tetere gun, ewe efinrin wewe, ewe ogbe ori akuko, a o se won papo pelu igo oti
sinaapu, eyo kan, a o wa da omi ti yoo po dada ti o ba jina, ti o tutu, a o ya si
mimo pelu Ps 24 x 1, 104 x 1, 33 x 1 a o ma fi fo oju ogbe naa, a o si maa mu
ninu re pelu

35. EGBOGI FUN GBOGBO KOKORO INU EJE: Ti ara ba n yun eniyan, tabi ara ba
nta eniyan, tabi kokoro nle si eniyan lara, kokoro eje ni o ma n fa, egbo akogun, a
o gun ti yoo kuna dada, a o da sinu igo tabi ike, a o da omi osan wewe si pelu, a o
ma mu ni aro ati ale.

36. Ewe kan wa ni ile Yoruba ti o Lagbara, ti o si ma nwo opolopo arun ati aisan
san kuro lara eniyan. Ewe naa ni a n pe ni Eyin olobe, ti ede oyinbo re nje
Phyllantusamarus (Ewe ara re je wewe) lara awon aisan ati arun ti ewe yi le
wo niyi.

1. HYPPENDIX: Eje ki a ma se ewe naa, ki a mu dada ni emeta ni oju mo.

2. AISAN STROKE, e je ki a ma se ewe yi ki a ma mu dede ni emeta ni ojumo, ki a


si ma fi jo ara ti stroke ban se.

3. ITO SUGAR: Eniti o ba ni aisan yii, ki o ma mu dada ni aro ki o to jeun ati ni ale
dada ati ni osan bi aago meji.

4. HYPERTENTION: Ki eni naa ma mu ni emerin ni ojumo ri wipe o mu fun bi osu


meta dada.

5. TOILET INFECTION: Ki eni naa ma mu bi eni mu omi, ki o si maa mu dada, ti


aisan naa yoo si tan.

6. FUN ATOSI OLOJO PIPE: E je ki a wa ewe naa, ki o po dada, ki a se, ki a si maa


mu dada ni emerin ni ojumo, ti a ba ti se ewe yii tan, e jowo e je ki a ya si mimo
pelu Ps 18 x 1, 24 x 3, 91 x 3. O daju, Olorun Oluwa yoo si wo wa san, ki a si pe
oruko Oluwa yi si inu re nigba meje (JEHOVAH RAPHA)
AWON IWOSAN TI A LE FI OYIN SE
Oyin wulo lopolopo, ninu awon kokoro ti Olorun seda, oyin je okan lara re, ti o lagbara,
igbe oyin ni oje adun fun iran eniyan bakanna o sin se ise iwosan fun iran eniyan.
Ninu Bibeli Woli kan wa ti o je wipe ounje re ni oyin, ti o ba gbawe, ti o ba fe jeun oyin
ni ounje re, oyin da pupo, o si tun wulo fun ara eniyan. Woli Johanu Onitebomi (Mat
3:4) leyin ti Jesu Olugbala ku tan, ti o si jade o farahan awon omo eyin re, o si tun
bere, won wipe eja bibu ati afara oyin die wa, Lk 24: 42 afara oyi wulo bakana ni oyin
na da.

1. TI NKAN OSU OBINRIN BAN SE SEGESEGE: Ki a lo alubosa ayu pomo omi osan
wewe, ki a da sinu oyin mimu ni sibi meta ni ojumom a o si ya si mimo pelu Ps
18 x , 24 x 1

2. FUN IWOSAN ATOSI: Omi osan jaganyin, pelu ayu a o da sinu oyin mimu, sibi
merin ni ojumo, ya si mimo pelu Ps 24 x 1.

3. FUN IWOSAN ENITI O SANRA: Ti o ba fe dinku, ki a se epo ara agbado ni ori ina,
ki a wa ma bu oyin die si bi tea, ki a ma mu laro ati lale, ki a si ya si mimo pelu
Ps 24 x 1 , 23 x 1

4. IWOSAN FUN INU OBINRIN TI O N GBONA: E je ki a lo ayu pelu oyin, ki a ma


mu ni sibi merin ni ojumo, ya si mimo pelu Ps 24 x 1.

5. IWOSAN FUN IBA REFUNREFUN: E je ki a lo ayu po pelu omi osan wewe pelu
eyin ibile kan, ati oyin gidi, ki a ma mu ni emeta ni ojumo, ki a si ya si mimo pelu
Ps 18 x 1.

6. IWOSAN TI ARA BA NGBONA: Omi ewuro ti a gbo, laifi omi si rara, a le fi iyo
gbo, a o po mo oyin gidi, a o ma mu sibi meji ni emeta ni ojumo, ya si mimo pelu
Ps 24 x 1, 91 x 1.

7. FUN IWOSAN ROPAROSE: Ito idaji eni ti o ni aisan naa, a o da po pelu oyin igan
ti odara, a o ya si mimo pelu Ps 24 x 3, 91 x 3, 40 x 3.

8. FUN EJE RIRU: A o lo ayu po pelu oyin igan, a o ma mu sibi meta ni ojumo, ya si
mimo pelu Ps 24 x 1.

9. FUN NKAN OMOKUNRIN LATI SISE DADA: A o fi ogede dudu, ti ati se je oyin
ninu abo, a o si ya si mimo pelu Ps 17 x 1, 27 x 1.

10. FUN IWOSAN INU RIRUN: A o po iyo mo oyin, a o ma mu ni emeta ni ojumo ya si


mimo pelu Ps 18 x 1.

11. FUN IWOSAN KOKORO ARA: A o lo eru awonka mo imi ojo, pelu etui bon, a o po
po pelu oyin, a o ma fi pa ara wa. Kokoro naa yo si gbe danu, ara yoo si jolo dada,
ya si mimo pelu Ps 24 x 1.
12. IWOSAN FUN ARA DIDAN: A o po oyin mo adin-agbon, a o ma fi pa ara wa ara
wa o si dan, ya si mimo pelu Ps 22 x 1, 40 x 1

13. IWOSAN FUN ARAN: A o wa omi osan wewe pelu oyin, a o ma mu ni sibi meta ni
ojumo, ya si mimo pelu Ps 17 x 1, 33 x 1, 109 x 1

14. IWOSAN FUN IKO EJE: Ki a lo orogbo, ki a da sinu oyin, ki a ma lo ni sibi kan ni
wakati meta meta, omode sibi kekere, ya si mimo pelu Ps 91 x 1.

15. IWOSAN FUN OMO TI O N TO SILE: Ki a ma mu sibi meji ni ale ki o to ma sun,


ki o si ma si be titi ito naa yo fi da.

16. IWOSAN FUN ATOGBE: Omi ewe ewuro da sinu oyin igan gidi, ma mu sibi merin
ni emeta ni ojumo, ya si mimo pelu Ps 24 x 1 , 18 x 1.

17. IWOSAN FUN OGBE INU: Ki iru eni bee ma mu sibi oyin meta ni aro, ki o to jeun

18. IWOSAN FUN IKO EGBE: Ki a po omi igbin po mo eyin, ki a ma mu ni sibi meta
ni emeta ni ojumo, ya si mimo pelu Ps 3 x 1, 91 x 1.

19. IWOSAN FUN JEDIJEDI: E je ki a lo efirin pelu omi osan wewe, papo mo oyin, ki
a mu sibi meta laro ati lale, ya si mimo pelu Ps 22 x 1, 18 x 1

20. IWOSAN FUN IKO IFE: A o lo atare po pelu alubosa ayu, pelu iyo ati orogbo pelu
oyin, a o ma mu ni sibi meji ni igba meta ni ojumo ya si mimo pelu Ps 24 x 1, 28
x 1, 17 x 1, 68 x 7

21. IWOSAN AROMOLEGUN: A o lo ewuro po mo oyin igan, a o ma fi pa ibiti o ba nro


wa, a o si ma mu sibi meta ni aro kutukutu, ya si mimo pelu Ps 91 x 7, 24 x 1,
17 x 1.

EYIN ARA MI, OHUN GBOGBO TI OLORUN DA, DARADARA NI O DA WON FUN
IWULO WA. ENIKENI YOWU TI O BA FI SE IKA, IRU ENI BE WA NINU EWU IDAJO
NLA. JOWO GBINYANU LATI SE RERE YO SI DARA FUN O.
ORO IPARI
Mo ki eyin ayanfe ti eni ore ofe nla, lati se alabapade iwe yii, mo fe ki e mo wipe ore
ofe nla ni eni, nitori wipe irufe iwe eto yii ko si fun eniyan kan lasan, bi kose fun
awon omo Woli, ti won nko ise Oluwa, ti won nko eko nipa imo Woli. Sugbon nipa
anu ati ore ofe krisiti, awa naa wa je anfaani re, mo fe ki e ri iwe yi bi ohun elo ti o
lagbara, bi ohun elo ti o le tun aye eniyan se, mo fe ki o kun fun igbagbo, iwo yoo si
ri ogo Olorun. Ko si eni ti ko le se eto ti o wa ninu yii, nitori Jesu ti fun wa ni ore
ofe, sugbon sa fun ese, gbe igbe aye iwa mimo, yo si dara fun o, mo daju wipe
Olorun ki gbo ti elese. Mo si kokoro ti o ti ilekun iwe eto yi sile fun gbogbo eni ti o
ba ni iwe yii lowo, ti kise ni ona aito. Nitori na jowo ma se eda iwe yi (Photocopy)
tabi ki o tun iwe yii te ni ona tie, ma gbagbe wipe edidi meta kan wa ti o ti iwe yii
nidi, jowo ma se ba ojo iwaju re je. Nitori ere aisoto. Oluwa yoo gbe o leke gbogbo
eto ti o wa ninu iwe yii, mo si ilekun re sile, ti o ba ti nse, yo maje fun o, ni ona
gbogbo, ti o ba lo fun omode, agba, onile ati alejo, oba, ijoye, eniyan alawo dudu,
ati alawo funfun ati gbogbo ohun ti o ba lo fun, ni ona ti o to loju Olorun, yoo ma
sise fun o ni oruko Baba Omo ati niti emi mimo (Amin). Jowo ma se te iwe yi ni ona
aito, tabi da ohunkohun ko ninu re, tabi se photocopy re, laigba ase lowo emi ti mo
ko iwe yii, yo si dara fun o.

E je ki a maa foju sona fun apa keji iwe yii, yio jade laipe, nibe ni a o tun ma baa
won eto miiran pade, eyi ti yoo wulo fun awa ti a je omo Woli ati Iranse Olorun
lapapo. Nipari e ma gbadura fun mi, ki e si ma gbagbe lati ma fi emi imore han,
nipa fifi ebun ti o ba dara ranse simi. Bakana e le pe mi fun awon ohun ti ko ba ye
yin, ninu awon eto naa, tabi ti e ba ni awon eto adura miiran ti e ba fe.

Ti o ba fe ba mi soro, o le pe ni pri ago mi 08185386093 tabi ki o ba mi soro ni


email: agbaramiko@gmail.com or prophetmichealagbaramiko@yahoo.com loni.

E ma foju sora fun iwe oruko Oluwa ati iwulo re yoo jade laipe ati awon iwe miiran.
Iwe awon ise iyanu ti o wa nini Bibeli ati awon ohun miiran wa fun tita (Apa kini ati
apa kej) nipari jowo ma se se ika, ire lope, oruko rere san ju wura ati fadaka lo,
idaniloju wa ninu iwe eto yii, gbogbo eto, egbogi ati lilo ogun gbogbo nnkan wonyi
ti ati lo, ti iyanu si nsele, Olorun si njerii agbara re, mo fi da yin loju leekan si wipe
gbogbo eto na, ni o sise ti e ba ti se ni ona ti a ni ki ese, dandan ni ki o ye ki o ri bi
o se ye ki ori. Alaafia Olorun ki o wa pelu yin titi de opin. (Amin)

Tiyin ninu ise Oluwa

Woli M.O. Agbaramiko

Potrebbero piacerti anche